Ògèrè Anthem
Ilu mi, Ilu Ògèrè – a song of belonging. This anthem celebrates the beauty, pride and enduring love of Ògèrè, sung by her sons and daughters wherever they may be.
- Ilu mi (2ce)
- Ilu Ògèrè
- O dara, O lewa
- Ni ‘lu to tobi
- Ibikibi to wun ki mo lewa lorile aye
- N ko le gbagbe
- Ilu Ògèrè
Ògèrè Eulogy (Oríkì Ògèrè)
Oríkì is the poetic praise of Ògèrè's lineage, valour and nobility. Recited at ceremonies and gatherings, it honours the town's founding ancestors, royalty, traditions, identity, and enduring spirit.
- Omo Iseje, Iseje afi epo lada
- Omo memu memu ma fi nu
- Omo ke magba ke magba, ekuru abi worawora, abi agbelepon bi ogede
- Omo Gbenlokun, omo Agbejoye, a gbe gege joye baba e.
- Omo Kankanbiina poke bi owula. A ti kekere moju ade.
- Omo Arolagbade, a nigi meta lehinkunle, ikan n so owo, ekeji n so ejigba ileke, eketa n so alaari, alaari baba aso.
- Omo Mojibade alate isiwu. Omo Morisagbara olode, to n fe gbogbo Ògèrè ni won.
- Omo Lidiyan. Omo Udomogun ibago. Omo Agun mareni
- Omo Eluku meden meden, ara Iraye afeleja.
- Omo Biraku ajaye. Omo Itajiren, abajeji leru.
- Omo ibiti ari eye, ti a ko roko, ibiti ari oko, ti a ko reye.
- Omo Idaren oro nuti. Omo Olumale ajogori.
- Omo Oyewo, oye wo sinu ile, oyi okuta sita.
- Omo Loti moyin teri ko kunsa.
- Omo Alagemo, abi ijo wene
- Omo Ule Gunsenmade. Omo Lowa-Lida, eni akoko de ilu Ògèrè.
- Omo Otunbade, agbe gbede.
- Omo Ugbun, Ugbun ja Oloko sa, Ugbun ma ta mi, ore mi ni ki o se.
- Omo Lipakala agbeni ma dein.
- Omo Yemogun atatameti, elebiripo iji miji.
Explore Ògèrè
Continue into the authoritative pages covering Ògèrè Rẹ́mọ’s history, traditional institution, community, development, enterprise and culture.